1 Corinthians 10:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ìdánwò kan tí ó dé ba yín bíkòṣe irú èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrin eniyan. Ṣugbọn Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé, kò ní jẹ́ kí ẹ rí ìdánwò tí ó ju èyí tí ẹ lè fara dà lọ. Ṣugbọn ní àkókò ìdánwò, yóo pèsè ọ̀nà àbáyọ, yóo sì mú kí ẹ lè fara dà á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ìdànwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó ti bá ènìyàn rí, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlórun, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ̀n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ́yin baà lè faradà á.