1 Corinthians 10:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Rárá o! Ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn abọ̀rìṣà fi ń rúbọ, ẹ̀mí burúkú ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọrun. N kò fẹ́ kí ẹ ní ìdàpọ̀ pẹlu àwọn ẹ̀mí burúkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ohun ti mo nwi nipe, ohun ti awọn Keferi fi nrubọ, nwọn fi nrubọ si awọn ẹ̃mi èṣu, kì si iṣe si Ọlọrun: emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ba awọn ẹmi èṣu ṣe ajọpin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rúbọ wọn sí àwọn ẹ̀mí èsù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù.