1 Corinthians 10:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní tèmi, mò ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó wu gbogbo eniyan ní gbogbo ọ̀nà. Kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani tèmi ni mò ń wá, bíkòṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani ọpọlọpọ eniyan, kí á lè gbà wọ́n là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani bi emi ti nwù gbogbo enia li ohun gbogbo, laiwá ere ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a le gbà wọn lã.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ṣè n gbìyanjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà.