1 Corinthians 10:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n mu nínú omi tí Kírísítì fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kírísítì. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú ihà náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára.