1 Corinthians 10:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ẹ má sì di abọ̀rìṣà bí àwọn mìíràn ninu wọn. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn eniyan náà jókòó láti jẹ ati láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣe àríyá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹyin má ṣe sin ère òrìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti jó.”