1 Corinthians 11:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ mọ̀ pé ní tiwa, a kò ní oríṣìí àṣà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ninu àwọn ìjọ Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba dabi ẹniti o fẹran iyàn jija, awa kò ni irú aṣa bẹ̃, tabi awọn ijọ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí ẹnìkẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní àṣà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrin ìjọ Ọlọ́run.