1 Corinthians 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nigbati ẹnyin ba njẹun, olukuluku nkọ́ jẹ onjẹ tirẹ̀, ebi a si mã pa ẹnikan, ọti a si mã pa ẹnikeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olukúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkèjì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara.