1 Corinthians 11:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kinla? ẹnyin kò ni ile nibiti ẹ o mã jẹ, ti ẹ o si mã mu? tabi ẹnyin ngàn ijọ Ọlọrun, ẹnyin si ndojutì awọn ti kò ni? Kili emi o wi fun nyin? emi o ha yìn nyin ninu eyi? emi kò yìn nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kí ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.