1 Corinthians 11:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun kí ó tó kúrò ní ilé, kí ìpéjọpọ̀ yín má baà jẹ́ ìdálẹ́bi fun yín. Nígbà tí mo bá dé, n óo ṣe ètò nípa àwọn nǹkan tí ó kù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ebi ba npa ẹnikẹni, ki o jẹun ni ile; ki ẹnyin ki o má bã pejọ fun ẹbi. Iyokù li emi ó si tò lẹsẹsẹ nigbati mo ba de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má baá mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá pé jọ. Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹsẹ.