1 Corinthians 12:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jẹ ìrora, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù níí máa bá a jẹ ìrora. Bí ara bá tu ẹ̀yà kan, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù ni yóo máa bá a yọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.