1 Corinthians 12:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oríṣìíríṣìí eniyan ni Ọlọrun yàn ninu ìjọ: àwọn kinni ni àwọn aposteli, àwọn keji, àwọn wolii; àwọn kẹta, àwọn olùkọ́ni; lẹ́yìn náà, àwọn oníṣẹ́ ìyanu, kí ó tó wá kan àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn tabi àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, tabi àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti darí ètò iṣẹ́ ìjọ, ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti sọ èdè àjèjì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni, lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti nínú ìjọ, Olọ́run ti yan àwọn àpósítélì àkọ́kọ́, èkéjì àwọn wòlíì, ẹni ẹ̀kẹta àwọn Olùkọ́, lẹ́yìn náà, àwọn tí ó ní òsìsẹ́ iṣẹ́ ìyanu, lẹ́yin náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmuláradá, àwọn Olùrànlọ́wọ́ àwọn alákòóso àwọn tí ń sọ onírúurú èdè.