1 Corinthians 13:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí nisinsinyii, à ń ríran bàìbàì ninu dígí. Ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ojú yóo kojú, a óo sì ríran kedere. Nisinsinyii, kò sí ohunkohun tí mo mọ̀ ní àmọ̀tán. Ṣugbọn nígbà náà, n óo ní ìmọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti mọ̀ mí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé nísinsìnyìí àwa ń ríran bàìbàì nínú àwòjìjì; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsinyìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mímọ̀ pẹ̀lú.