1 Corinthians 13:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìfẹ́ kò lópin. Ní ti ọ̀rọ̀ wolii, wọn yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Ní ti àwọn èdè àjèjì wọn yóo di ohun tí a kò gbúròó mọ́. Ní ti ìmọ̀, yóo di ohun tí kò wúlò mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìfẹ̀ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bún ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.