1 Corinthians 14:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu Òfin, ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Oluwa wí pé, “N óo bá àwọn eniyan yìí sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn eniyan tí ó ń sọ èdè àjèjì, ati láti ẹnu àwọn àlejò. Sibẹ wọn kò ní gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A ti kọ ọ ninu ofin pe, Nipa awọn alahọn miran ati elete miran li emi ó fi bá awọn enia yi sọrọ; sibẹ nwọn kì yio gbọ temi, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A tí kọ ọ́ nínú òfin pé, “Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn àti elété mìíràn ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀; síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,” ni Olúwa wí.