1 Corinthians 14:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí gbogbo yín bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, bí ẹnìkan tí ó jẹ́ alaigbagbọ tabi ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ bá wọlé, yóo gbọ́ ohun tí ó jẹ́ ìbáwí ati ohun tí yóo mú un yẹ ara rẹ̀ wò ninu ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi gbogbo nyin ba nsọtẹlẹ, ti ẹnikan ti kò gbagbọ́ tabi ti kò li ẹ̀kọ́ bá wọle wá, gbogbo nyin ni yio fi òye ẹ̀ṣẹ yé e, gbogbo nyin ni yio wadi rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbi tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀.