1 Corinthians 14:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ará, kí ni kókó ohun tí à ń sọ? Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, bí ẹnìkan bá ní orin, tí ẹnìkan ní ẹ̀kọ́, tí ẹnìkan ní ìfihàn, tí ẹnìkan ní èdè àjèjì, tí ẹnìkan ní ìtumọ̀ fún èdè àjèjì, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun gbogbo fún ìdàgbà ìjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ è é ha ti ṣe, ki ni ki àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin pé jọ pọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Sáàmù kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan, ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró.