1 Corinthians 15:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ó ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn nígbà tí ó sọ pé, “Gbogbo nǹkan ni ó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀,” ó dájú pé ẹnìkan ni kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀: ẹni náà sì ni Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ Kristi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori o ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati o wipe ohun gbogbo li a fi sabẹ rẹ̀, o daju pe, on nikanṣoṣo li o kù, ti o fi ohun gbogbo si i labẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí ó ti fí ohun gbogbo sábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fí sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkanṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kírísítì.