1 Corinthians 15:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí gbogbo nǹkan bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tán, ni Ọmọ fúnrarẹ̀ yóo wá bọ́ sí ìkáwọ́ Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀, kí Ọlọrun lè jẹ́ olórí ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a ba si fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ tan, nigbana li a ó fi Ọmọ tikararẹ̀ pẹlu sabẹ ẹniti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o le jasi ohun gbogbo li ohun gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkárarẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.