1 Corinthians 16:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi àbùkù kàn án. Ẹ ṣe ètò ìrìn àjò fún un ní alaafia, kí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, nítorí èmi ati àwọn arakunrin ń retí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.