1 Corinthians 16:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nípa ti arakunrin wa Apolo, mo gbà á níyànjú gidigidi pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín pẹlu àwọn arakunrin yòókù. Ṣugbọn ó pinnu pé òun kò fẹ́ wá ní àkókò yìí. Ó ń bọ̀ nígbà tí ó bá yá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní ti Àpólò arákùnrin wa, mo bẹ́ẹ̀ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbá tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.