1 Corinthians 16:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ mo bẹ nyin, ará (ẹ sá mọ̀ ile Stefana, pe awọn ni akọso Akaia, ati pe, nwọn si ti fi ara wọn fun iṣẹ-iranṣẹ awọn enia mimọ́),
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ sá mọ ilé Sítéfánà, pé àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jésù ní Ákáyà, àti pé, wọn sì tí fí ará wọn fún iṣẹ́-iránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.