1 Corinthians 2:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ẹ̀dá alààyè wo ni ó mọ ohun tí ó wà ninu eniyan kan bíkòṣe ẹ̀mí olúwarẹ̀ tí ó wà ninu rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn nǹkan Ọlọrun: kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Ẹ̀mí Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori tani ninu enia ti o mọ̀ ohun enia kan, bikoṣe ẹmí enia ti o wà ninu rẹ̀? bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o mọ̀ ohun Ọlọrun, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni tó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bíkòse Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnraa rẹ̀.