1 Corinthians 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ní tiwa, kì í ṣe ẹ̀mí ti ayé ni a gbà. Ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó fi fún wa, kí á lè mọ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fún wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awa ti gbà, kì iṣe ẹmi ti aiye, bikoṣe Ẹmí ti iṣe ti Ọlọrun; ki awa ki o le mọ̀ ohun ti a fifun wa li ọfẹ lati ọdọ Ọlọrun wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́.