1 Corinthians 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn enia nipa ti ara kò gbà ohun ti Ẹmí Ọlọrun wọnni: nitoripe wère ni nwọn jasi fun u: on kò si le mọ̀ wọn, nitori nipa ti Ẹmí li a fi nwadi wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí kò bá jẹ́ ti Ẹ̀mí kò lè gba àwọn ohun tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mi Mímọ́, nítorí wọ́n jẹ́ ohun wèrè sí, kò sì le ye e, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn.