1 Corinthians 3:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ta ni Apolo? Ta ni Paulu? Ṣebí iranṣẹ ni wọ́n, tí ẹ ti ipasẹ̀ wọn di onigbagbọ? Olukuluku wọn jẹ́ iṣẹ́ tirẹ̀ bí Ọlọrun ti rán an.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbagbọ́, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Àpólò ha jẹ́, kí ni Pọ́ọ̀lù sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípaṣẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olukúlúkù.