1 Corinthians 4:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wa, ṣugbọn àwa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí. A di ohun ẹ̀sín fún gbogbo ayé. A di pàǹtí fún gbogbo eniyan títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn nkẹgàn wa, awa mbẹ̀bẹ: a ṣe wa bi ohun ẹgbin aiye, bi ẽri ohun gbogbo titi di isisiyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsinyìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.