1 Corinthians 4:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbààrún olùkọ́ni nínú Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kírísítì Jésù ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìn rere.