1 Corinthians 4:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdí tí mo ṣe rán Timoti si yín nìyí, ẹni tí ó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ fún mi, ati olóòótọ́ ninu nǹkan ti Oluwa. Òun ni yóo ran yín létí àwọn ohun tí mo fi ń ṣe ìwà hù ninu ìgbé-ayé titun ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ gbogbo àwọn ìjọ níbi gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni mo ṣe rán Timotiu si nyin, ẹniti iṣe ọmọ mi olufẹ ati olododo ninu Oluwa, ẹniti yio ma mu nyin ranti ọ̀na mi ti o wà ninu Kristi, gẹgẹ bi mo ti nkọ́ni ninu gbogbo ijọ nibigbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni mo ṣe rán Tìmótíù sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.