1 Corinthians 4:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará, mo fi ara mi ati Apolo ṣe àpẹẹrẹ ohun tí à ń sọ nítorí yín, kí ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára wa, pé kí ẹ má ṣe tayọ ohun tí ó wà ní àkọsílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹnìkejì lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ará, nkan wọnyi ni mo ti fi ṣe apẹrẹ ara mi ati Apollo nitori nyin; ki ẹnyin ki o le ti ipa wa kọ́ ki ẹ maṣe ré ohun ti a ti kọwe rẹ̀ kọja, ki ẹnikan ninu nyin ki o máṣe ti itori ẹnikan gberaga si ẹnikeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kíyèsí i pé, mo ti fi ara mi àti Àpólò ṣe àpẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe titorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”