1 Corinthians 4:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé gbogbo nǹkan ti tẹ yín lọ́rùn! Ẹ ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ gbàgbé wa sẹ́yìn, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí jọba! Kì bá wù mí kí ẹ jọba nítòótọ́ kí àwa náà lè ba yín jọba!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A sá tẹ́ nyin lọrùn nisisiyi, a sá ti sọ nyin di ọlọrọ̀ nisisiyi, ẹnyin ti njọba laisi wa: iba si wu mi ki ẹnyin ki o jọba, ki awa ki o le jùmọ jọba pẹlu nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jọba pẹ̀lú yín!