1 Corinthians 5:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí mo kọ si yín ni pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tí a bá ń pè ní onigbagbọ tí ó ń hùwà àgbèrè, tabi ti ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà, tabi abanijẹ́, tabi ọ̀mùtí, tabi oníjìbìtì. Ẹ má tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè ni arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹ̃ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń wí nínú ìwé sí i yín pé, ẹ kò gbọdọ̀ darapọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ara rẹ̀ ni arákùnrin, ṣùgbọ́n tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè tàbí wọ̀bìà, ìbọ̀rìṣà àti ẹlẹ́gàn tàbí ìmutípara àti alọ́nilọ́wọ́gbà. Ẹ má ṣe bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ oúnjẹ pọ̀ rárá.