1 Corinthians 5:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Èwo ni tèmi láti dá alaigbagbọ lẹ́jọ́? Ṣebí àwọn onigbagbọ ara yín ni ẹ̀ ń dá lẹ́jọ́? Ọlọrun ni ó ń ṣe ìdájọ́ àwọn alaigbagbọ. Ẹ yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ewo ni temi lati mã ṣe idajọ awọn ti mbẹ lode? ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í ṣe iṣẹ́ mi láti máa ṣe ìdájọ́ (àwọn aláìgbàgbọ́) àwọn tí wọn kò sí nínú ìjọ. Dájúdájú iṣẹ́ tiwa ni láti ṣe ìdájọ́ àti láti fi ọwọ́ líle mú àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ.