1 Corinthians 5:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ jẹ ki a ṣe ajọ na, kì iṣe pẹlu iwukara atijọ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu iwukara arankàn ati ìwa buburu; bikoṣe pẹlu aiwukara ododo ati otitọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankan àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.