1 Corinthians 6:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ̀n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jésù Kírísítì Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.