1 Corinthians 6:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ ayé? Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ óo ṣe ìdájọ́ ayé, ó ti wá jẹ́ tí ẹ kò fi lè ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó kéré jùlọ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò ha mọ̀ pe awọn enia mimọ́ ni yio ṣe idajọ aiye? Njẹ bi o ba ṣepe a ó tipasẹ nyin ṣe idajọ aiye, ẹnyin ha ṣe alaiyẹ lati ṣe idajọ awọn ọ̀ran ti o kere julọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpaṣẹ̀ yín ni a ti ṣe ìdájọ́ ayé, kí ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrin ara yín.