1 Corinthians 7:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ní ọ̀rọ̀ fún ẹ̀yin yòókù, (èrò tèmi ni o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Oluwa wa.) Bí ọkunrin onigbagbọ kan bá ní aya tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu aya rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ọkọ má ṣe kọ̀ ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn iyokù ni mo wi fun, kì iṣe Oluwa: bi arakunrin kan ba li aya ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe kọ̀ ọ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo fẹ́ fi àwọn àmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.