1 Corinthians 7:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ẹni tí kì í ṣe onigbagbọ bá yàn láti fi ẹnìkejì tí ó jẹ́ onigbagbọ sílẹ̀, kí ó fi í sílẹ̀. Kò sí ọ̀ranyàn fún ọkọ tabi aya tí ó jẹ́ onigbagbọ ninu irú ọ̀ràn báyìí. Kí ẹ jọ wà ní alaafia ní ipò tí Ọlọrun pè yín sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi alaigbagbọ́ na ba lọ, jẹ ki o mã lọ. Arakunrin tabi arabinrin kan kò si labẹ ìde, nitori irú ọ̀ran bawọnni: ṣugbọn Ọlọrun pè wa si alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Onígbàgbọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin náà kò sí lábẹ́ idè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlààfíà.