1 Corinthians 7:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí, ta ni ó mọ̀, bóyá ìwọ aya ni yóo gba ọkọ rẹ là? Tabi ta ni ó mọ̀, ìwọ ọkọ, bóyá ìwọ ni o óo gba aya rẹ là?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ aya, bi iwọ ó gbà ọkọ rẹ là? tabi iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ ọkọ, bi iwọ ó gbà aya rẹ là?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe mọ̀ pé ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ.