1 Corinthians 7:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo fẹ́ rí i pé ẹ kò ní ìpayà kan tí yóo mú ọkàn yín wúwo. Ẹni tí kò bá ní iyawo yóo máa páyà nípa nǹkan Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó wu Oluwa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi nfẹ ki ẹnyin ki o wà laiṣe aniyàn. Ẹniti kò gbeyawo ama tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, bi yio ti ṣe le wù Oluwa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi siṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn.