1 Corinthians 7:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ọkàn rẹ̀ yóo pín sí meji. Obinrin tí kò bá lọ́kọ tabi obinrin tí ó bá jẹ́ wundia yóo máa páyà nípa nǹkan ti Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà tí yóo fi ya ara ati ọkàn rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Oluwa. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ní ọkọ yóo máa páyà nípa àwọn nǹkan ayé, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iyatọ si wà pẹlu larin obinrin ti a gbe ni iyawo ati wundia. Obinrin ti a kò gbe ni iyawo a mã tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, ki on ki o le jẹ mimọ́ li ara ati li ẹmí: ṣugbọn ẹniti a gbé ni iyawo a ma tọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù ọkọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí ó bá wà nílé ọkọ, irú ìṣòro kan náà ni ó dojú kọ. Ọmọbìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa ṣàkìtiyan láti tẹ́ Olúwa lọ́rùn ní gbogbo ìwà àti ìṣe àti ní tí ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe àkíyèsí ohun púpọ̀, yóò máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.