1 Corinthians 8:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a fi rúbọ fún oriṣa. A mọ̀ pé, “Gbogbo wa ni a ní ìmọ̀,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn irú ìmọ̀ yìí a máa mú kí eniyan gbéraga, ṣugbọn ìfẹ́ ní ń mú kí eniyan dàgbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ṢUGBỌN niti awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe gbogbo wa li o ni ìmọ. Ìmọ a mã fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbe-ni-ro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìsinsinyìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀, ìmọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní i gbéni ró.