1 Corinthians 8:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó ní ìmọ̀ yìí. Nítorí àwọn mìíràn wà tí èèwọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà ti mọ́ lára tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé, bí wọn bá jẹ irú oúnjẹ yìí, bí ìgbà tí wọn ń bọ̀rìṣà ni. Nítorí wọn kò ní ẹ̀rí ọkàn tí ó lágbára, jíjẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àbùkù fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsinyìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rì-ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́.