1 Corinthians 9:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tabi kò dájú pé nítorí tiwa ni ó ṣe sọ ọ́? Dájúdájú nítorí tiwa ni. Nítorí ó yẹ kí ẹni tí ń roko kí ó máa roko pẹlu ìrètí láti pín ninu ìkórè oko, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ó ń pa ọkà ní ìrètí láti pín ninu ọkà náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi o nsọ eyi patapata nitori wa? Nitõtọ nitori wa li a ṣe kọwe yi: ki ẹniti ntulẹ ki o le mã tulẹ ni ireti; ati ẹniti npakà, ki o le ni ireti ati ṣe olubapin ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a se kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìretí láti ní ipin nínú ìkórè.