1 Corinthians 9:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ láti jẹ lára yín, ṣé ẹ̀tọ́ tiwa kò ju tiwọn lọ? Ṣugbọn a kò lo anfaani tí a ní yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ à ń fara da ohun gbogbo kí á má baà fa ìdínà fún ìyìn rere Kristi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àwọn ẹlòmírán bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù? Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má baà ṣe ìdènà fún ìyìn rere Kírísítì.