1 Corinthians 9:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn Juu, èmi a máa di Juu kí n lè jèrè wọn. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí ó gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sábẹ́ Òfin Mose, kí n lè jèrè àwọn tí ó gba ètò ti Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò gba ètò ti Òfin Mose fúnra mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun awọn Ju mo dabi Ju, ki emi ki o le jère awọn Ju; fun awọn ti mbẹ labẹ ofin, bi ẹniti mbẹ labẹ ofin, ki emi ki o le jère awọn ti mbẹ labẹ ofin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn baà lè tẹ́tí sí ìwàásù ìyìn rere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kírísítì. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin.