1 Corinthians 9:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nsáre ije, gbogbo nwọn ni nsáre nitõtọ, ṣugbọn ẹnikan ni ngbà ère na? Ẹ sáre bẹ̃, ki ẹnyin ki o le ri gbà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú rẹ̀ ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò kìn-ín-ní. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ baà le borí.