1 Corinthians 9:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí gbogbo àwọn tí ń sáré ìje a máa kó ara wọn ní ìjánu. Wọ́n ń ṣe èyí kí wọ́n lè gba adé tí yóo bàjẹ́. Ṣugbọn adé tí kò lè bàjẹ́ ni tiwa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati olukuluku ẹniti njijàdu ati bori a ma ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo. Njẹ nwọn nṣe e lati gbà adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti ki idibajẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti borí nínú eré ìdíje, ẹ ní láti sẹ́ ara yín nínú ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó lè fá yín sẹ́yín nínú sísa gbogbo agbára yín. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run tí kò lè bàjẹ́ láéláé.