1 John 1:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìyè yìí farahàn, a ti rí i, a sì ń jẹ́rìí rẹ̀. Ìyè ainipẹkun yìí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó ti farahàn fún wa, ni a wá ń kéde fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
(Ìye na si ti farahàn, awa si ti ri i, awa si njẹri, awa si nsọ ti ìye ainipẹkun na fun nyin, ti o ti mbẹ lọdọ Baba, ti o si farahàn fun wa;)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa.