1 John 2:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin baba, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ̀yin ọmọde, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ Baba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi nkọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin ti ṣẹgun ẹni buburu nì. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitori ẹnyin ti mọ̀ Baba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe, Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n, nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba.