1 John 2:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin ọmọ mi, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí; bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé Aṣòdìsí-Kírísítì ń bọ̀ wá, àní nísìnsin yìí, púpọ̀ Aṣòdì-sí-Kírísítì ló ń bẹ. Nípa èyí ni àwa fí mọ́ pé ìgbà ìkẹ́yìn ni èyí.